ÌWÉ ÒWE 11:24-31

ÌWÉ ÒWE 11:24-31 YCE

Ẹnìkan wà tíí máa ṣe ìtọrẹ àánú káàkiri, sibẹsibẹ àníkún ni ó ń ní, ẹnìkan sì wà tí ó háwọ́, sibẹsibẹ aláìní ni. Ẹni tí ó bá lawọ́ yóo máa ní àníkún, ẹni tí ó bá jẹ́ kí ọkàn ẹlòmíràn balẹ̀, ọkàn tirẹ̀ náà yóo balẹ̀. Ẹni tí ó bá ń kó oúnjẹ pamọ́, yóo gba ègún sórí, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ta oúnjẹ, yóo rí ibukun gbà. Ẹni tí ó bá ń wá ire, yóo rí ojurere, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ibi, ibi yóo bá a. Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóo rẹ̀ dànù bí òdòdó, ṣugbọn olódodo yóo rú bí ewé tútù. Ẹni tí ó bá mú ìyọnu dé bá ìdílé rẹ̀ yóo jogún òfo, òmùgọ̀ ni yóo sì máa ṣe iranṣẹ ọlọ́gbọ́n. Èso olódodo ni igi ìyè, ṣugbọn ìwà aibikita fún òfin a máa paniyan. Bí a óo bá san ẹ̀san fún olódodo láyé, mélòó-mélòó ni ti eniyan burúkú ati ẹlẹ́ṣẹ̀.