Àwọn òwe Solomoni nìwọ̀nyí: Ọlọ́gbọ́n ọmọ á máa mú kí inú baba rẹ̀ dùn, ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ a máa kó ìbànújẹ́ bá ìyá rẹ̀. Ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú kò lérè, ṣugbọn òdodo a máa gba eniyan lọ́wọ́ ikú. OLUWA kì í jẹ́ kí ebi pa olódodo, ṣugbọn ó máa ń da ìfẹ́ ọkàn eniyan burúkú rú. Ìmẹ́lẹ́ máa ń fa òṣì, ṣugbọn ẹni tí ó bá tẹpá mọ́ṣẹ́ yóo di ọlọ́rọ̀. Ọlọ́gbọ́n ní ọmọ tí ó kórè ní àkókò ìkórè, ṣugbọn ọmọ tí ó bá ń sùn lákòókò ìkórè a máa kó ìtìjú báni. Ibukun wà lórí olódodo, ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu, a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu. Ayọ̀ ni ìrántí olódodo, ṣugbọn orúkọ eniyan burúkú yóo di ohun ìgbàgbé. Ọlọ́gbọ́n a máa pa òfin mọ́, ṣugbọn òmùgọ̀ onísọkúsọ yóo di ẹni ìparun. Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ eniyan, yóo máa rìn láìfòyà, ṣugbọn àṣírí alágàbàgebè yóo tú. Ẹni tí bá ń ṣẹ́jú sí ni láti sọ̀rọ̀ èké, a máa dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀, ṣugbọn ẹni tí bá ń báni wí ní gbangba, ń wá alaafia. Ẹnu olódodo dàbí orísun omi ìyè, ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu, a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu.
Kà ÌWÉ ÒWE 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÌWÉ ÒWE 10:1-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò