ÌWÉ ÒWE 1:10-16

ÌWÉ ÒWE 1:10-16 YCE

Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, o ò gbọdọ̀ gbà. Bí wọn bá wí pé, “Tẹ̀lé wa ká lọ, kí á lọ sápamọ́ láti paniyan, kí á lúgọ de aláìṣẹ̀, jẹ́ kí á gbé wọn mì láàyè kí á gbé wọn mì lódidi bí isà òkú, a óo rí àwọn nǹkan olówó iyebíye kó, ilé wa yóo sì kún fún ìkógun. Ìwọ ṣá darapọ̀ mọ́ wa, kí á sì jọ lẹ̀dí àpò pọ̀.” Ọmọ mi, má bá wọn kẹ́gbẹ́, má sì bá wọn rìn, nítorí ọ̀nà ibi ni ẹsẹ̀ wọn máa ń yá sí, wọ́n a sì máa yára láti paniyan.