Ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa nígbà gbogbo. Mo tún wí: ẹ máa yọ̀. Ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo eniyan pé ẹ ní ẹ̀mí ìfaradà. Oluwa fẹ́rẹ̀ dé! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohunkohun dààmú yín, ṣugbọn ninu gbogbo adura ati ẹ̀bẹ̀ yín, ẹ máa fi àwọn ìbéèrè yín siwaju Ọlọrun pẹlu ọpẹ́. Alaafia Ọlọrun, tí ó tayọ òye eniyan yóo pa ọkàn ati èrò yín mọ́ ninu Kristi Jesu. Ní ìparí, ẹ̀yin ará, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe òtítọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá lọ́lá, gbogbo nǹkan tí ó bá tọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ́ mímọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá fa eniyan mọ́ra, gbogbo nǹkan tí ó bá ní ìròyìn rere, àwọn ni kí ẹ máa kó lé ọkàn. Àwọn ohun tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ mi, tí ẹ bá lọ́wọ́ mi, tí ẹ ti gbọ́ lẹ́nu mi, tí ẹ ti rí ninu ìwà mi, àwọn ni kí ẹ máa ṣe. Ọlọrun alaafia yóo sì wà pẹlu yín. Mo láyọ̀ pupọ ninu Oluwa nítorí ọ̀rọ̀ mi tún ti bẹ̀rẹ̀ sí sọjí ninu èrò yín. Kò sí ìgbà kan tí ẹ kì í ronú nípa mi ṣugbọn ẹ kò rí ààyè láti ṣe àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbèrò. N kò sọ èyí nítorí mo ṣe aláìní, nítorí mo ti kọ́ láti máa ní ìtẹ́lọ́rùn ní ipòkípò tí mo bá wà. Mo mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu àìní, mo sì mọ bí eniyan ti ń gbé ìgbé-ayé ninu ọpọlọpọ ọrọ̀. Nípòkípò tí mo bá wà, ninu ohun gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn, kì báà jẹ́ ninu ebi tabi ayo, ninu ọ̀pọ̀ tabi àìní.
Kà FILIPI 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: FILIPI 4:4-12
5 Days
Bestselling author Max Lucado explores God’s treatment plan for anxiety found in Philippians 4:4–8. As you follow this prescription – celebrating God’s goodness, asking for his help, leaving your concerns with him, and meditating on good things – you will experience God’s peace. While anxiety is a part of life, it doesn’t have to dominate your life.
The letter Paul wrote to the church in Philippi has traveled across generations to nourish and challenge our hearts and minds today. This five-day devotional gives you a taste of the book of Philippians, many centuries from when God authored it through Paul. May God fill you with wonder and expectation as you read this letter of joy! Because these are not just Paul’s words to an ancient church—these are God’s words to you.
7 days
What if there’s a better way to fight the endless worries that keep you up at night? Real rest is available—maybe closer than you think. Replace panic with peace through this 7-day Bible Plan from Life.Church, accompanying Pastor Craig Groeschel’s message series Anxious for Nothing.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò