Sibẹ ẹ ṣeun tí ẹ bá mi pín ninu ìpọ́njú mi. Ẹ̀yin ará Filipi mọ̀ pé ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìyìn rere mi, nígbà tí mo kúrò ní Masedonia, kò sí ìjọ kan tí ó bá mi lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ fífúnni lẹ́bùn ati gbígba ẹ̀bùn jọ fúnni àfi ẹ̀yin nìkan ṣoṣo. Nítorí nígbà tí mo wà ní Tẹsalonika kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan mọ, ó tó ẹẹmeji tí ẹ fi nǹkan ranṣẹ sí mi. Kì í ṣe ẹ̀bùn ni mò ń wá, ṣugbọn mò ń wá ọpọlọpọ èso fún anfaani yín. Ìwé ẹ̀rí nìyí fún ohun gbogbo tí ẹ fún mi, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù. Mo ní ànító nígbà tí mo rí ohun tí ẹ fi rán Epafiroditu sí mi gbà. Ó dàbí òróró olóòórùn dídùn, bí ẹbọ tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, tí inú Ọlọrun dùn sí. Ọlọrun mi yóo pèsè fún gbogbo àìní ẹ̀yin náà, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ̀ tí ó lógo nípasẹ̀ Jesu Kristi. Kí ògo kí ó jẹ́ ti Ọlọrun Baba wa lae ati laelae. Amin. Ẹ kí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí ó jẹ́ ti Kristi Jesu. Àwọn arakunrin tí ó wà lọ́dọ̀ mi ki yín. Gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun ki yín, pàápàá jùlọ àwọn ti ìdílé Kesari. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu ẹ̀mí yín.
Kà FILIPI 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: FILIPI 4:14-23
7 Days
Lent: a 40-day season of reflection and repentance. It’s a nice thought, but what does practicing Lent actually look like? Over the next 7 days, discover five spiritual habits you can start doing during Lent to help you prepare your heart for Resurrection Sunday—and beyond.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò