FILIPI 2:6-11

FILIPI 2:6-11 YCE

ẹni tí ó wá ní àwòrán Ọlọrun, sibẹ kò ka ipò jíjẹ́ ọ̀kan pẹlu Ọlọrun sí ohun tí ìbá gbé léjú. Ṣugbọn ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀, ó gbé àwòrán ẹrú wọ̀, ó wá farahàn ní àwọ̀ eniyan. Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu títí dé ojú ikú, àní ikú lórí agbelebu. Nítorí náà ni Ọlọrun ṣe gbé e ga ju ẹnikẹ́ni lọ; ó sì fún un ní orúkọ tí ó ga ju gbogbo orúkọ yòókù lọ, pé ní orúkọ Jesu ni gbogbo ẹ̀dá yóo máa wólẹ̀, lọ́run ati láyé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀; gbogbo ẹ̀dá yóo sì máa jẹ́wọ́ pé, “Jesu Kristi ni Oluwa,” fún ògo Ọlọrun Baba.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú FILIPI 2:6-11