FILIPI 1:19-20

FILIPI 1:19-20 YCE

nítorí mo mọ̀ pé àyọrísí rẹ̀ ni pé a óo dá mi sílẹ̀ nípa adura yín ati nípa àtìlẹ́yìn Ẹ̀mí Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí igbẹkẹle ati ìrètí mi pé n kò ní rí ohun ìtìjú kan. Ṣugbọn bí mo ti máa ń gbé Kristi ga ninu ara mi pẹlu ìgboyà nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ gan-an náà ni n óo tún máa gbé e ga nisinsinyii ìbáà jẹ́ pé mo wà láàyè tabi pé mo kú.