Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi mú kí iṣẹ́ ìyìn rere túbọ̀ tàn kalẹ̀ ni. Ó ti wá hàn sí gbogbo àwọn tí ó wà ní ààfin ati gbogbo àwọn eniyan yòókù pé nítorí ti Kristi ni mo ṣe wà ninu ẹ̀wọ̀n. Èyí fún ọpọlọpọ ninu àwọn onigbagbọ tí wọ́n mọ ìdí tí mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n ní ìgboyà gidigidi láti máa waasu ìyìn rere láì bẹ̀rù. Àwọn ẹlòmíràn ń waasu Kristi nítorí owú ati nítorí pé wọ́n fẹ́ràn asọ̀. Àwọn ẹlòmíràn sì wà tí wọn ń waasu Kristi pẹlu inú rere. Àwọn kan ń fi ìfẹ́ waasu Kristi nítorí wọ́n mọ̀ pé nítorí ti ọ̀rọ̀ ìyìn rere ni wọ́n ṣe sọ mí sẹ́wọ̀n. Àwọn kan ń sọ̀rọ̀ Kristi nítorí ohun tí wọn óo rí gbà níbẹ̀, kì í ṣe pẹlu inú kan, wọ́n rò pé àwọn lè mú kí ìrora mi ninu ẹ̀wọ̀n pọ̀ sí i. Kí ni àyọrísí gbogbo èyí? Lọ́nà kan tabi lọ́nà mìíràn, ìbáà ṣe pẹlu ẹ̀tàn ni, tabi pẹlu òtítọ́ inú, a sá ń waasu Kristi, èyí ni ó mú inú mi dùn. Inú mi yóo sì máa dùn ni, nítorí mo mọ̀ pé àyọrísí rẹ̀ ni pé a óo dá mi sílẹ̀ nípa adura yín ati nípa àtìlẹ́yìn Ẹ̀mí Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí igbẹkẹle ati ìrètí mi pé n kò ní rí ohun ìtìjú kan. Ṣugbọn bí mo ti máa ń gbé Kristi ga ninu ara mi pẹlu ìgboyà nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ gan-an náà ni n óo tún máa gbé e ga nisinsinyii ìbáà jẹ́ pé mo wà láàyè tabi pé mo kú. Nítorí pé Kristi ni mo wà láàyè fún ní tèmi, bí mo bá sì kú, èrè ni ó jẹ́. Bí mo bá wà láàyè ninu ẹran-ara, iṣẹ́ tí ó lérè ni ó jẹ́ fún mi. N kò tilẹ̀ mọ èyí tí ǹ bá yàn. Ọkàn mi ń ṣe meji; ọkàn mi kan fẹ́ pé kí á dá mi sílẹ̀, kí n lọ sọ́dọ̀ Jesu, nítorí èyí ni ó dára jùlọ. Ṣugbọn ó tún ṣàǹfààní bí mo bá wà láàyè ninu ẹran-ara, nítorí tiyín. Èyí dá mi lójú, nítorí náà mo mọ̀ pé n óo wà láàyè. Bí mo bá wà ní ọ̀dọ̀ gbogbo yín, yóo mú ìlọsíwájú ati ayọ̀ ninu igbagbọ wá fun yín. Èyí yóo mú kí ìṣògo yín ninu Kristi Jesu lè pọ̀ sí i nítorí mi, nígbà tí mo bá tún yọ si yín.
Kà FILIPI 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: FILIPI 1:12-26
30 Days
Discover the wisdom of Oswald Chambers, author of My Utmost for His Highest, in this treasury of insights about joy. Each reading features quotations from Chambers along with questions for your own personal reflection. As he inspires and challenges you with his simple and direct biblical wisdom, you will find yourself wanting to spend more time communicating with God.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò