MATIU 7:24-27

MATIU 7:24-27 YCE

“Nítorí náà, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí ó bá fi ṣe ìwà hù dàbí ọlọ́gbọ́n eniyan kan, tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta. Òjò rọ̀; àgbàrá dé, ẹ̀fúùfù sì kọlu ilé náà; ṣugbọn kò wó, nítorí ìpìlẹ̀ rẹ̀ wà lórí àpáta. “Ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí kò bá fi ṣe ìwà hù, ó dàbí òmùgọ̀ eniyan kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. Òjò rọ̀, àgbàrá dé, ẹ̀fúùfù sì kọlu ilé náà. Ó bá wó! Wíwó rẹ̀ sì bani lẹ́rù lọpọlọpọ.”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ