MATIU 6:32-34

MATIU 6:32-34 YCE

Nítorí gbogbo nǹkan wọnyi ni àwọn abọ̀rìṣà ń lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo wọn. Ṣugbọn ẹ kọ́kọ́ máa wá ìjọba Ọlọrun ná ati òdodo rẹ̀, gbogbo nǹkan wọnyi ni a óo fi kún un fún yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn nípa nǹkan ti ọ̀la; nítorí ọ̀la ni nǹkan ti ọ̀la wà fún; wahala ti òní nìkan ti tó fún òní láì fi ti ọ̀la kún un.

Àwọn fídíò fún MATIU 6:32-34