MATIU 6:10-13
MATIU 6:10-13 YCE
kí ìjọba rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti dárí ji àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ wá. Má fà wá sinu ìdánwò, ṣugbọn gbà wá lọ́wọ́ èṣù.’







