MATIU 5:2-11

MATIU 5:2-11 YCE

Ó bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ń kọ́ wọn pé: “Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó jẹ́ òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí Ọlọrun yóo tù wọ́n ninu. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, nítorí wọn yóo jogún ayé. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn aláàánú, nítorí Ọlọrun yóo ṣàánú wọn. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́, nítorí wọn yóo rí Ọlọrun. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó ń mú kí alaafia wà láàrin àwọn eniyan, nítorí Ọlọrun yóo pè wọ́n ní ọmọ rẹ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí eniyan ń ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. “Ayọ̀ ń bẹ fun yín, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín, tí wọ́n bá ń fi èké sọ ọ̀rọ̀ burúkú lóríṣìíríṣìí si yín nítorí mi.

Àwọn fídíò fún MATIU 5:2-11

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún MATIU 5:2-11

MATIU 5:2-11 - Ó bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ń kọ́ wọn pé:
“Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó jẹ́ òtòṣì ní ẹ̀mí,
nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.
Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀,
nítorí Ọlọrun yóo tù wọ́n ninu.
Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀,
nítorí wọn yóo jogún ayé.
Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ,
nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó.
Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn aláàánú,
nítorí Ọlọrun yóo ṣàánú wọn.
Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́,
nítorí wọn yóo rí Ọlọrun.
Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó ń mú kí alaafia wà láàrin àwọn eniyan,
nítorí Ọlọrun yóo pè wọ́n ní ọmọ rẹ̀.
Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí eniyan ń ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo,
nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.
“Ayọ̀ ń bẹ fun yín, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín, tí wọ́n bá ń fi èké sọ ọ̀rọ̀ burúkú lóríṣìíríṣìí si yín nítorí mi.