MATIU 4:17-24

MATIU 4:17-24 YCE

Láti àkókò yìí ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu pé, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba ọ̀run súnmọ́ ìtòsí.” Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji kan, Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀. Wọ́n ń da àwọ̀n sí inú òkun, nítorí apẹja ni wọ́n. Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, kì í ṣe ẹja ni ẹ óo máa pamọ́, eniyan ni ẹ óo máa fà wá.” Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Bí ó ti kúrò níbẹ̀ tí ó lọ siwaju díẹ̀ sí i, ó rí àwọn arakunrin meji mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀. Wọ́n wà ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó bá pè wọ́n. Lẹsẹkẹsẹ, wọ́n fi ọkọ̀ ati baba wọn sílẹ̀, wọ́n tẹ̀lé e. Jesu wá ń kiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo oríṣìíríṣìí àrùn sàn lára àwọn eniyan. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo Siria. Àwọn eniyan ń gbé gbogbo àwọn tí ó ní oríṣìíríṣìí àrùn ati àìlera wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati àwọn tí ẹ̀mí Èṣù ń dà láàmú, ati àwọn tí wárápá mú ati àwọn arọ; ó sì ń wò wọ́n sàn.

Àwọn fídíò fún MATIU 4:17-24