MATIU 26:6-13

MATIU 26:6-13 YCE

Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, ninu ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí, obinrin kan wọlé tọ̀ ọ́ wá tí ó ní ìgò òróró iyebíye olóòórùn dídùn, ni ó bá bẹ̀rẹ̀ sí tú u sí orí Jesu níbi tí ó ti ń jẹun. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu rí i, inú bí wọn. Wọ́n ní, “Kí ni ìdí irú òfò báyìí? Nítorí títà ni à bá ta òróró yìí ní owó iyebíye tí à bá fi fún àwọn talaka.” Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, nítorí náà, ó wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń da obinrin yìí láàmú sí? Nítorí iṣẹ́ rere ni ó ṣe sí mi lára. Nígbà gbogbo ni ẹ ní àwọn talaka láàrin yín, ṣugbọn ẹ kò ní máa rí mi láàrin yín nígbà gbogbo. Nítorí nígbà tí obinrin yìí da òróró yìí sí mi lára, ó ṣe é fún ìsìnkú mi ni. Mò ń sọ fun yín dájúdájú, níbikíbi tí a bá ń waasu ìyìn rere ní gbogbo ayé, a óo máa sọ nǹkan tí obinrin yìí ṣe ní ìrántí rẹ̀.”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ