Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila sọ́dọ̀, ó fún wọn ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ati láti máa ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àrùn ati àìsàn. Orúkọ àwọn aposteli mejila náà nìwọ̀nyí: Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; lẹ́yìn náà Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀. Filipi ati Batolomiu, Tomasi ati Matiu agbowó-odè, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Tadiu. Simoni ará Kenaani ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. Àwọn mejila yìí ni Jesu rán níṣẹ́, ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má gba ọ̀nà ìlú àwọn tí kì í ṣe Juu lọ; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má wọ ìlú àwọn ará Samaria. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ tọ àwọn aguntan ilé Israẹli tí ó sọnù lọ. Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa waasu pé, ‘Ìjọba ọ̀run súnmọ́ tòsí!’ Ẹ máa wo aláìsàn sàn; ẹ máa jí àwọn òkú dìde; ẹ máa sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́; ẹ máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ rí agbára wọnyi gbà. Ọ̀fẹ́ ni kí ẹ máa lò wọ́n. Ẹ má fi owó wúrà tabi fadaka tabi idẹ sinu àpò yín. Ẹ má mú àpò tí wọ́n fi ń ṣagbe lọ́wọ́ lọ. Ẹ má mú ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ meji. Ẹ má wọ bàtà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má mú ọ̀pá lọ́wọ́. Oúnjẹ òṣìṣẹ́ tọ́ sí i. “Bí ẹ bá dé ìlú tabi ìletò kan, ẹ fẹ̀sọ̀ wádìí bí ẹni tí ó yẹ kan bá wà níbẹ̀; lọ́dọ̀ rẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò níbẹ̀. Nígbà tí ẹ bá wọ inú ilé kan lọ, ẹ kí wọn pé, ‘Alaafia fún ilé yìí.’ Bí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ bá wà ninu ilé náà, kí alaafia tí ẹ ṣe kí ó wà níbẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí alaafia tí ẹ ṣe kí ó pada sọ́dọ̀ yín. Bí ẹnìkan kò bá gbà yín sílé, tabi tí kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ yín, ẹ jáde kúrò ninu ilé tabi ìlú náà, kí ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, yóo sàn fún ilẹ̀ Sodomu ati ti Gomora ní ọjọ́ ìdájọ́, ju ìlú náà lọ! “Ẹ ṣe akiyesi pé mò ń ran yín lọ bí aguntan sáàrin ìkookò. Nítorí náà ẹ gbọ́n bí ejò, kí ẹ sì níwà tútù bí àdàbà.
Kà MATIU 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 10:1-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò