LUKU 11:34-36
LUKU 11:34-36 YCE
Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá ríran kedere, gbogbo ara rẹ yóo ní ìmọ́lẹ̀. Ṣugbọn bí ojú rẹ kò bá ríran, gbogbo ara rẹ ni yóo ṣókùnkùn. Nítorí náà kí ẹ ṣọ́ra kí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà ninu yín má baà jẹ́ òkùnkùn. Bí gbogbo ara rẹ bá ní ìmọ́lẹ̀, tí kò sí ibìkan tí ó ṣókùnkùn, ńṣe ni yóo mọ́lẹ̀ bí ìgbà tí àtùpà bá tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ lára.”


