ẸKÚN JEREMAYA 3:37-41

ẸKÚN JEREMAYA 3:37-41 YCE

Ta ló pàṣẹ nǹkankan rí tí ó sì rí bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé OLUWA ló fi ọwọ́ sí i? Àbí kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá Ògo ni rere ati burúkú ti ń jáde? Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè kan yóo fi máa ráhùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí á yẹ ara wa wò, kí á tún ọ̀nà wa ṣe, kí á sì yipada sí ọ̀dọ̀ OLUWA. Ẹ jẹ́ kí á gbé ojú wa sókè, kí á ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun ọ̀run