JUDA 1:8-11

JUDA 1:8-11 YCE

Bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí fún àwọn eniyan wọnyi lónìí. Àlá tí wọn ń lá, fún ìbàjẹ́ ara wọn ni. Wọ́n tàpá sí àwọn aláṣẹ. Wọ́n ń sọ ìsọkúsọ sí àwọn ẹ̀dá ọ̀run tí ó lógo. Nígbà tí Mikaeli, olórí àwọn angẹli pàápàá ń bá Èṣù jiyàn, tí wọ́n ń jìjàdù òkú Mose, kò tó sọ ìsọkúsọ sí i. Ohun tí ó sọ ni pé, “Oluwa yóo bá ọ wí.” Ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi a máa sọ ìsọkúsọ nípa ohunkohun tí kò bá ti yé wọn. Àwọn nǹkan tí ó bá sì yé wọn, bí nǹkan tíí yé ẹranko ni. Ohun tí ń mú ìparun bá wọn nìyí. Ó ṣe fún wọn! Wọ́n ń rìn ní ọ̀nà Kaini. Wọ́n tẹra mọ́ ọ̀nà ẹ̀tàn Balaamu nítorí ohun tí wọn yóo rí gbà. Wọ́n dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ bíi Kora, wọ́n sì parun.