JONA 1:4-6

JONA 1:4-6 YCE

Ṣugbọn OLUWA gbé ìjì kan dìde lójú omi òkun, afẹ́fẹ́ náà le tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ ojú omi fẹ́rẹ̀ ya. Ẹ̀rù ba àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀, olukuluku bá bẹ̀rẹ̀ sí ké pe oriṣa rẹ̀, wọ́n ń da ẹrù wọn tí ó wà ninu ọkọ̀ sinu òkun kí ọkọ̀ lè fúyẹ́. Ṣugbọn Jona ti lọ dùbúlẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀, ó sì ti sùn lọ fọnfọn. Olórí àwọn tí wọn ń tu ọkọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí ò ń sùn, olóorun? Dìde, ké pe ọlọrun rẹ, bóyá a jẹ́ ṣàánú wa, kí á má baà ṣègbé.”