Báwo ni mo ṣe lè bá a rojọ́? Kí ni kí n sọ? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi, sibẹsibẹ n kò lè dá a lóhùn. Ẹ̀bẹ̀ nìkan ni mo lè bẹ̀ fún àánú, lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ẹ̀sùn kàn mí. Bí mo bá pè é pé kó wá gbọ́, tí ó sì dá mi lóhùn, sibẹ n kò lè gbàgbọ́ pé yóo dẹtí sílẹ̀ gbọ́rọ̀ mi. Nítorí pé ó ti fi ìjì tẹ̀ mí mọ́lẹ̀, ó sì sọ egbò mi di pupọ láìnídìí; kò ní jẹ́ kí n mí, ìbànújẹ́ ni ó fi kún ọkàn mi. Bí ó bá ṣe ti pé kí á dán agbára wò ni, agbára rẹ̀ pọ̀ tayọ! Bí ó bá sì jẹ́ pé ti ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́, ta ló lè pè é lẹ́jọ́? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi, sibẹsibẹ ọ̀rọ̀ ẹnu mi yóo di ẹ̀bi rù mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́ṣẹ̀, sibẹsibẹ yóo fihàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí. N kò lẹ́bi, sibẹ n kò ka ara mi kún, ayé sú mi. Kò sí ìyàtọ̀ lójú rẹ̀, nítorí náà ni mo fi wí pé, ati ẹlẹ́bi ati aláìlẹ́bi ni ó ti parun. Nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀, tí ó já sí ikú òjijì, a máa fi aláìṣẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà ninu ìdààmú wọn. A ti fi ayé lé àwọn ẹni ibi lọ́wọ́, ó ti di àwọn adájọ́ rẹ̀ lójú. Bí kì í bá ṣe òun Ọlọrun, ta ló tún tó bẹ́ẹ̀? “Ọjọ́ ayé mi ń sáré lọ tete, kò sí ẹyọ ọjọ́ kan tí ó dára ninu wọn. Wọ́n sáré kọjá lọ bíi koríko ojú omi, bí ẹyẹ idì tí ń fò fẹ̀ẹ̀ lọ bá ohun tí ó fẹ́ pa. Bí mo bá sọ pé kí n gbàgbé ìráhùn mi, kí n sì tújúká; kí n má ronú mọ́; ẹ̀rù ìrora mi á bẹ̀rẹ̀ sí bà mí, nítorí mo mọ̀ pé o kò ní gbà pé n kò dẹ́ṣẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá mi lẹ́bi, kí ni mo tún ń ṣe wahala lásán fún? Ọṣẹ yòówù tí mo lè fi wẹ̀, kódà kí n fi omi yìnyín fọ ọwọ́, sibẹ o óo tì mí sinu kòtò ìdọ̀tí. Kódà n óo di ohun ìríra sí aṣọ ara mi.
Kà JOBU 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOBU 9:14-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò