Àwọn ọkunrin mẹtẹẹta náà kò dá Jobu lóhùn mọ́, nítorí pé ó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀. Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, ní ìdílé Ramu bá bínú sí Jobu, nítorí pé ó dá ara rẹ̀ láre dípò Ọlọrun. Ó bínú sí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹtẹẹta pẹlu, nítorí pé wọn kò mọ èsì tí wọ́n lè fún Jobu mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dá a lẹ́bi. Elihu ti fẹ́ bá Jobu sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn ó dákẹ́, nítorí àwọn àgbà tí wọ́n jù ú lọ ni wọ́n ń sọ̀rọ̀. Ṣugbọn nígbà tí Elihu rí i pé àwọn mẹtẹẹta kò lè fún Jobu lésì mọ́, inú bí i. Ó ní,
“Àgbàlagbà ni yín, ọmọde sì ni mí,
nítorí náà ni ojú fi ń tì mí,
tí ẹ̀rù sì ń bà mí láti sọ èrò ọkàn mi.
Mo ní kí ẹ̀yin àgbà sọ̀rọ̀,
kí ọ̀rọ̀ yín sì fa ọgbọ́n yọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí yín.
Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu eniyan,
tíí ṣe èémí Olodumare,
ni ó ń fún eniyan ní ìmọ̀.
Kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ni wọ́n gbọ́n,
tabi pé arúgbó nìkan ni ó mọ òye ohun tó tọ́, tó yẹ.
Nítorí náà, ‘Ẹ fetí sílẹ̀,
kí èmi náà lè sọ èrò ọkàn mi.’
“Mo farabalẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin ń sọ̀rọ̀,
mo fetí sí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yín,
nígbà tí ẹ̀ ń ronú ohun tí ẹ fẹ́ sọ,
Mo farabalẹ̀ fun yín,
ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí ó lè ko Jobu lójú,
kí ó sì fi àṣìṣe rẹ̀ hàn án,
tabi kí ó fún un lésì àwọn àwíjàre rẹ̀.
Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà wí pé, ‘A ti di ọlọ́gbọ́n,
Ọlọrun ló lè ṣe ìdájọ́ rẹ̀, kì í ṣe eniyan.’
Èmi kọ́ ni Jobu ń bá wí, ẹ̀yin ni,
n kò sì ní dá a lóhùn bí ẹ ṣe dá a lóhùn.