Elifasi ará Temani bá dáhùn pé, “Ǹjẹ́ eniyan lè wúlò fún Ọlọrun? Nítòótọ́, bí eniyan tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ara rẹ̀ ni ó wúlò fún. Ǹjẹ́ jíjẹ́ olódodo rẹ̀ ṣe ohun rere kan fún Olodumare, tabi kí ni èrè rẹ̀ bí ó bá jẹ́ ẹni pípé? Ṣé nítorí pé o bẹ̀rù rẹ̀ ni ó ṣe bá ọ wí, tí ó sì ń dá ọ lẹ́jọ́? Ṣebí ìwà ibi rẹ ló pọ̀; tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lópin? O gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ àwọn arakunrin rẹ láìnídìí, O bọ́ wọn sí ìhòòhò goloto. O kò fún aláàárẹ̀ ní omi mu, o kọ̀ láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ. Ẹni tí ó lágbára gba ilẹ̀, ẹni tí ó lọ́lá sì ń gbé inú rẹ̀. O lé àwọn opó jáde lọ́wọ́ òfo, o sì ṣẹ́ aláìní baba lápá. Nítorí náà ni okùn dídẹ fi yí ọ ká, tí jìnnìjìnnì sì bò ọ́ lójijì. Ìmọ́lẹ̀ rẹ ti di òkùnkùn, o kò ríran, ìgbì omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀. “Ṣebí Ọlọrun wà lókè ọ̀run Ó ń wo àwọn ìràwọ̀ nísàlẹ̀ àní àwọn tí wọ́n ga jùlọ, bí ó ti wù kí wọ́n ga tó! Sibẹsibẹ ò ń bèèrè pé, ‘Kí ni Ọlọrun mọ̀?’ Ṣé ó lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn biribiri? Ìkùukùu tí ó nípọn yí i ká, tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè ríran, ó sì ń rìn ní òfuurufú ojú ọ̀run. “Ṣé ọ̀nà àtijọ́ ni ìwọ óo máa tẹ̀lé; ọ̀nà tí àwọn ẹni ibi rìn? A gbá wọn dànù, kí àkókò wọn tó tó, a ti gbá ìpìlẹ̀ wọn lọ. Wọ́n sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀, kí ni ìwọ Olodumare lè fi wá ṣe?’ Sibẹsibẹ ó fi ìṣúra dáradára kún ilé wọn– ṣugbọn ìmọ̀ràn ẹni ibi jìnnà sí mi.
Kà JOBU 22
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOBU 22:1-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò