OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín, tí wọ́n ń mu yín gbẹ́kẹ̀lé irọ́. Ohun tí wọn fẹ́ lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ, kì í ṣe ẹnu èmi OLUWA ni wọ́n ti gbọ́ ọ. Wọ́n ń sọ lemọ́lemọ́ fún àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí pé, yóo dára fún wọn. Wọ́n ń wí fún gbogbo àwọn tí wọn ń tẹ̀lé àìgbọràn ọkàn wọn pé ibi kò ní bá wọn.”
Mo ní, “Èwo ninu wọn ló wà ninu ìgbìmọ̀ OLUWA tí ó ti ṣe akiyesi tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Èwo ninu wọn ni ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sì gbà á gbọ́? Ẹ wo ibinu OLUWA bí ó ṣe ń jà bí ìjì! Ó ti fa ibinu yọ. Ó sì ń jà bí ìjì líle. Yóo tú dà sí orí àwọn eniyan burúkú. Inú OLUWA kò ní rọ̀ títí yóo fi ṣe ohun tí ó pinnu lọ́kàn rẹ̀. Yóo ye wọn nígbà tí ọjọ́ ìkẹyìn bá dé.”
OLUWA ní, “N kò rán àwọn wolii níṣẹ́, sibẹsibẹ aré ni wọ́n ń sá lọ jíṣẹ́. N kò bá wọn sọ̀rọ̀, sibẹsibẹ wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Bí wọn bá ti bá mi pé ní ìgbìmọ̀ ni, wọn ìbá kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn eniyan mi, wọn ìbá yí wọn pada kúrò lọ́nà ibi tí wọn ń rìn, ati iṣẹ́ ibi tí wọn ń ṣe.
“Ṣé nítòsí nìkan ni mo ti jẹ́ Ọlọrun ni, èmi kì í ṣe Ọlọrun ọ̀nà jíjìn? Ǹjẹ́ ẹnìkan lè sápamọ́ sí ìkọ̀kọ̀ kan tí n kò fi ní rí i? Kì í ṣe èmi ni mo wà ní gbogbo ọ̀run tí mo sì tún wà ní gbogbo ayé? Mo gbọ́ ohun tí àwọn wolii tí wọn ń fi orúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ń sọ, tí wọn ń sọ pé, àwọn lá àlá, àwọn lá àlá! Irọ́ yóo ti pẹ́ tó lọ́kàn àwọn wolii èké tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn. Wọ́n ṣebí àwọn lè fi àlá tí olukuluku wọn ń rọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀ mú àwọn eniyan mi gbàgbé orúkọ mi, bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé mi, tí wọn ń tẹ̀lé oriṣa Baali. Kí àwọn wolii tí wọn lá àlá máa rọ́ àlá wọn, ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ó sọ ọ́ pẹlu òtítọ́. Báwo ni a ṣe lè fi ìyàngbò wé ọkà? Ṣebí bí iná ni ọ̀rọ̀ mi rí, ati bí òòlù irin tíí fọ́ àpáta sí wẹ́wẹ́? Nítorí náà, mo dojú ìjà kọ àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ tí wọn gbọ́ lẹ́nu ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi ni mo sọ ọ́. Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ ti ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlá irọ́, tí wọn ń rọ́ àlá irọ́ wọn, tí wọn fí ń ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà pẹlu irọ́ ati ìṣekúṣe wọn, nígbà tí n kò rán wọn níṣẹ́, tí n kò sì fún wọn láṣẹ. Nítorí náà wọn kò ṣe àwọn eniyan wọnyi ní anfaani kankan. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”