ÀWỌN ADÁJỌ́ 4:6-7

ÀWỌN ADÁJỌ́ 4:6-7 YCE

Ó ranṣẹ pe Baraki, ọmọ Abinoamu, ní Kedeṣi, tí ó wà ní Nafutali, ó wí fún un pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ń pàṣẹ fún ọ pé kí o lọ kó àwọn eniyan rẹ̀ jọ ní òkè Tabori. Kó ẹgbaarun (10,000) eniyan ninu ẹ̀yà Nafutali ati Sebuluni jọ. N óo ti Sisera olórí ogun Jabini jáde láti pàdé rẹ lẹ́bàá odò Kiṣoni pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, n óo sì fà á lé ọ lọ́wọ́.”