OLUWA ní: “Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu iranṣẹ mi ẹ̀yin ọmọ Israẹli, àyànfẹ́ mi. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ẹlẹ́dàá yín wí, ẹni tí ó ṣẹ̀dá yín láti inú oyún, tí yóo sì ràn yín lọ́wọ́: Ẹ má bẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi, Jeṣuruni, ẹni tí mo yàn. “N óo tú omi sórí ilẹ̀ tí òùngbẹ ń gbẹ n óo sì ṣe odò sórí ilẹ̀ gbígbẹ. N óo tú ẹ̀mí mi sórí àwọn ọmọ yín, n óo da ibukun mi sórí arọmọdọmọ yín, wọn óo rúwé bíi koríko inú omi àní, bíi igi wilo lẹ́bàá odò tí ń ṣàn. “Ẹnìkan yóo wí pé, ‘OLUWA ló ni mí.’ Ẹnìkejì yóo pe ara rẹ̀ ní orúkọ Jakọbu. Ẹlòmíràn yóo kọ ‘Ti OLUWA ni’ sí apá rẹ̀ yóo máa fi orúkọ Israẹli ṣe àpèjá orúkọ rẹ̀.”
Kà AISAYA 44
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: AISAYA 44:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò