HEBERU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Àwọn onigbagbọ kan tí wọn ń dojú kọ ọpọlọpọ ìṣòro àtakò, tí wọ́n sì wà ninu ewu kíkọ ẹ̀sìn igbagbọ sílẹ̀ ni wọ́n kọ Ìwé sí Àwọn Heberu sí. Ẹni tí ó kọ ìwé náà gbà wọ́n ní ìyànjú ninu igbagbọ wọn pé, fífi hàn tí Jesu fi bí Ọlọrun ti rí hàn wá ni ìfihàn òtítọ́ ati ti ìkẹyìn nípa Ọlọrun. Ninu àlàyé rẹ̀ lórí ìfihàn yìí, ó tẹnu mọ́ àwọn òtítọ́ mélòó kan: (1) Jesu ni Ọmọ ayérayé Ọlọrun tí ó ti ipa ìjìyà ati ìfaradà kọ́ nípa bí a ti ń gbọ́ràn sí Baba lẹ́nu nítòótọ́. Nítorí pé Jesu jẹ́ Ọmọ Ọlọrun, ó ju àwọn wolii inú Majẹmu Laelae lọ, kì í ṣe ẹgbẹ́ àwọn angẹli tabi Mose pàápàá. (2) Ọlọrun ti sọ gbangba pé Jesu jẹ́ alufaa ayérayé tí ó ju àwọn alufaa inú Majẹmu Laelae lọ. (3) Nípasẹ̀ Jesu ni onigbagbọ ti rí ìgbàlà ninu ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀rù, ati ikú, ati pé Jesu tí ó jẹ́ Olórí Alufaa ni ó pèsè ìgbàlà tòótọ́. Àwòjíìji lásán ni ìlànà ẹ̀sìn ati ìfi-ẹran-rúbọ ti ẹ̀sìn àwọn Heberu jẹ́ ní ẹ̀gbẹ́ ìgbàlà tòótọ́ yìí.
Paulu mẹ́nuba àpẹẹrẹ igbagbọ àwọn eniyan pataki ninu ìran Israẹli (Orí 11), ó sì rọ àwọn olùka ìwé rẹ̀ láti túbọ̀ máa jẹ́ olóòótọ́. Ninu orí kejila ó tún rọ àwọn olùka ìwé rẹ̀ láti máa ṣe olóòótọ́ títí dé òpin. Ó ní kí wọ́n ṣá tẹjúmọ́ Jesu, kí wọ́n farada ìjìyàkíjìyà ati inúnibíni- kínúnibíni tí wọ́n lè bá pàdé. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ràn ati ìkìlọ̀ mìíràn ni ẹni tí ó kọ ìwé náà fi parí rẹ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: Kristi fi Ọlọrun hàn ní ọ̀nà tí ó pé 1:1-3
Bí Kristi ṣe ju àwọn angẹli lọ 1:4–2:18
Bí Kristi ṣe ju Mose ati Joṣua lọ 3:1–4:13
Bí Kristi ṣe tayọ gbogbo alufaa yòókù 4:14–7:28
Bí Kristi ṣe ju Majẹmu laelae lọ 8:1–9:28
Bí Kristi ṣe ju gbogbo ẹbọ yòókù lọ 10:1-39
Bí ìfẹ́ ṣe ju gbogbo nǹkan lọ 11:1–12:29
Ọ̀rọ̀ ìyànjú ìkẹyìn ati ọ̀rọ̀ ìparí 13:1-25

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

HEBERU Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa