JẸNẸSISI 34

34
Wọ́n fi Ipá bá Dina Lòpọ̀
1Ní ọjọ́ kan, Dina, ọmọbinrin tí Lea bí fún Jakọbu jáde lọ kí àwọn obinrin kan ní ìlú Ṣekemu. 2Nígbà tí Ṣekemu ọmọ Hamori, ará Hifi, tíí ṣe ọmọ ọba ìlú náà rí i, ó fi ipá mú un, ó sì bá a lòpọ̀ tipátipá. 3Ọkàn rẹ̀ fà sí Dina ọmọ Jakọbu, ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fún un. 4Ṣekemu bá lọ sọ fún Hamori, baba rẹ̀, pé kí ó fẹ́ ọmọbinrin náà fún òun.
5Jakọbu ti gbọ́ pé ó ti ba Dina, ọmọ rẹ̀ jẹ́, ṣugbọn àwọn ọmọ rẹ̀ wà pẹlu àwọn ẹran ninu pápá, Jakọbu kò sọ nǹkankan títí tí wọ́n fi dé. 6Hamori baba Ṣekemu tọ Jakọbu wá láti bá a sọ̀rọ̀. 7Nígbà tí àwọn ọmọ Jakọbu pada dé sílé, tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, inú bí wọn gidigidi nítorí bíbá tí Ṣekemu bá Dina lòpọ̀ pẹlu ipá yìí jẹ́ ìwà àbùkù gbáà ní Israẹli, irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò tọ́ sí ẹnikẹ́ni láti hù. 8Ṣugbọn Hamori bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní, “Ọkàn Ṣekemu, ọmọ mi, fà sí arabinrin yín, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fún un kí ó fi ṣe aya. 9Ẹ jẹ́ kí á jọ máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ ara wa, ẹ máa fi àwọn ọmọbinrin yín fún wa, kí àwa náà máa fi àwọn ọmọbinrin wa fún yín. 10A óo jọ máa gbé pọ̀, ibi tí ó bá wù yín ni ẹ lè gbé, ibi tí ẹ bá fẹ́ ni ẹ ti lè ṣòwò, tí ẹ sì lè ní ohun ìní.”
11Ṣekemu tún wí fún baba ati àwọn arakunrin omidan náà pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yọ́nú sí mi, ohunkohun tí ẹ bá ní kí n san, n óo san án. 12Iyekíye tí ó bá wù yín ni kí ẹ bèèrè fún owó orí iyawo, n óo san án, ẹ ṣá ti fi omidan náà fún mi.”
13Ọgbọ́n ẹ̀tàn ni àwọn ọmọ Jakọbu fi dá Ṣekemu ati Hamori, baba rẹ̀ lóhùn, nítorí bíbà tí ó ba Dina, arabinrin wọn jẹ́. 14Wọ́n wí fún wọn pé, “Ìtìjú gbáà ni ó jẹ́, pé kí a fi ọmọbinrin wa fún ẹni tí kò kọlà abẹ́, a kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. 15Ohun kan ṣoṣo tí ó lè mú kí ọ̀rọ̀ náà ṣeéṣe ni pé kí ẹ̀yin náà dàbí wa, kí gbogbo ọkunrin yín kọlà abẹ́. 16Nígbà náà ni a óo tó máa fi ọmọ wa fun yín tí àwa náà yóo máa fẹ́ ọmọ yín, a óo máa gbé pọ̀ pẹlu yín, a óo sì di ọ̀kan. 17Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò gbà láti kọlà abẹ́, a óo mú ọmọbinrin wa, a óo sì máa lọ.”
18Ọ̀rọ̀ wọn dùn mọ́ Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀ ninu. 19Ọdọmọkunrin náà kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀, nítorí pé ó fẹ́ràn ọmọbinrin Jakọbu lọpọlọpọ. Ninu gbogbo ìdílé ọmọkunrin yìí, òun ni ó jẹ́ eniyan pataki jùlọ.
20Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀ bá lọ sí ẹnubodè ìlú, wọ́n sọ fún àwọn ọkunrin ìlú náà pé, 21“Ìbágbé àwọn eniyan wọnyi tuni lára pupọ, ẹ jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ wa, kí wọ́n máa tà, kí wọ́n máa rà, ilẹ̀ yìí tóbi tó, ó gbà wọ́n. Ẹ jẹ́ kí á máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn, kí àwọn náà sì máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wa. 22Ohun kan ṣoṣo ni wọ́n ní kí á ṣe kí á lè jọ máa gbé pọ̀, kí á sì di ọ̀kan, wọ́n ní olukuluku ọkunrin wa gbọdọ̀ kọlà abẹ́ gẹ́gẹ́ bíi tiwọn. 23Ṣebí gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo ohun ìní wọn ni yóo di tiwa? Ẹ ṣá jẹ́ kí á gbà fún wọn, wọn yóo sì máa bá wa gbé.” 24Gbogbo àwọn ará ìlú náà gba ohun tí Hamori ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀ wí, gbogbo ọkunrin sì kọlà abẹ́.
25Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí ará kan wọ́n, meji ninu àwọn ọmọ Jakọbu, Simeoni ati Lefi, arakunrin Dina, mú idà wọn, wọ́n jálu àwọn ará ìlú náà lójijì, wọ́n sì pa gbogbo ọkunrin wọn. 26Wọ́n fi idà pa Hamori pẹlu, ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Wọ́n mú Dina jáde kúrò ní ilé Ṣekemu, wọ́n sì bá tiwọn lọ. 27Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Jakọbu wá kó gbogbo ohun ìní àwọn ará ìlú náà nítorí pé wọ́n ba arabinrin wọn jẹ́. 28Wọ́n kó gbogbo aguntan wọn, gbogbo mààlúù wọn, gbogbo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, ati gbogbo ohun tí ó wà nílé ati èyí tí ó wà ninu pápá.
29Ati gbogbo dúkìá wọn, àwọn ọmọ wọn ati àwọn aya wọn, gbogbo wọn ni wọ́n kó lẹ́rú, wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé wọn pẹlu. 30Jakọbu sọ fún Simeoni ati Lefi pé, “Irú ìyọnu wo ni ẹ kó mi sí yìí? Ẹ sọ mí di ọ̀tá gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ yìí, láàrin àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. Àwa nìyí, a kò pọ̀ jù báyìí lọ. Tí wọ́n bá kó ara wọn jọ sí mi, wọn óo run mí tilé-tilé.”
31Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “Àwa kò lè gbà kí ó ṣe arabinrin wa bí aṣẹ́wó.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JẸNẸSISI 34: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa