ISIKIẸLI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ní nǹkan bíi ẹgbẹta ọdún ó dín mẹrinla kí á tó bí OLUWA wa (586 B.C.), ni ogun kó Jerusalẹmu. Wolii Isikiẹli wà ní ìgbèkùn ní Babiloni ní ọdún bíi mélòó kan ṣáájú àkókò yìí, ati lẹ́yìn rẹ̀. Ìpín mẹfa pataki ni ó wà ninu Ìwé Isikiẹli: (1) Ìpè Isikiẹli sí iṣẹ́ wolii. (2) Àwọn ìkìlọ̀ nípa ìdájọ́ Ọlọrun lórí àwọn eniyan náà ati nípa ìṣubú ati ìparun Jerusalẹmu. (3) Ìdájọ́ OLUWA lórí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń ni àwọn eniyan OLUWA lára, ati àwọn tí wọ́n ṣì wọ́n lọ́nà. (4) Lẹ́yìn tí ogun kó Jerusalẹmu, OLUWA ranṣẹ ìtùnú sí àwọn eniyan rẹ̀ ó sì ṣèlérí pé ọjọ́ iwájú yóo dára. (5) Àsọtẹ́lẹ̀ ibi nípa Gogu. (6) Àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Tẹmpili tí wọn yóo tún kọ́ yóo ti rí, ati pé ó gbọdọ̀ wà ní mímọ́.
Isikiẹli jẹ́ ẹni tí ó ní igbagbọ tó jinlẹ̀ ati òye tó ga. Ọ̀pọ̀ ninu awọn àròfín rẹ̀ ni ó wá nipa ìran, tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn iṣẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ eyi tí a ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ ninu ìṣe alápẹẹrẹ tó fi ara hàn gbangba. Isikiẹli tẹnumọ ṣíṣe pataki lati ní ọkàn ati ẹ̀mí titun, ati pé olúkúlùkù ni yóò dáhùn fun ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀. Bakan náà ni ó kéde ìrètí rẹ̀ fun ìmúdọ̀tun ìgbé-ayé orilẹ-èdè Israeli. Gẹ́gẹ́ bí alufaa ati wòlíì, ó ní ìfẹ́ pataki fun Tẹmpili ati bí a ṣe nilo lati gbé ìgbé-ayé ìwà mímọ́.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọlọrun pe Isikiẹli 1:1–3:27
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun tí yóo dé bá Jerusalẹmu 4:1–24:27
Ìdájọ́ Ọlọrun lórí àwọn orílẹ̀-èdè 25:1–32:32
Ìlérí Ọlọrun nípa àwọn eniyan rẹ̀ 33:1–37:28
Àsọtẹ́lẹ̀ ibi nípa Gogu 38:1–39:29
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Tẹmpili ati ilẹ̀ náà ní ọjọ́ iwájú yóo ti rí 40:1–48:35

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ISIKIẸLI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa