ẸKISODU 7:11-12

ẸKISODU 7:11-12 YCE

Farao bá pe gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n, ati àwọn oṣó, ati àwọn pidánpidán tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Ijipti, àwọn náà pa idán, wọ́n ṣe bí Aaroni ti ṣe. Olukuluku wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá wọn sì di ejò ṣugbọn ọ̀pá Aaroni gbé gbogbo ọ̀pá tiwọn mì.