ẸKISODU 23:10-19

ẸKISODU 23:10-19 YCE

“Ọdún mẹfa ni kí o fi máa fúnrúgbìn sórí ilẹ̀ rẹ kí o sì fi máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ̀. Ṣugbọn ní ọdún keje, o gbọdọ̀ fi oko náà sílẹ̀ kí ó sinmi, kí àwọn talaka ninu yín náà lè rí oúnjẹ jẹ, kí àwọn ẹranko sì jẹ ninu èyí tí àwọn talaka bá jẹ kù. Bẹ́ẹ̀ ni o gbọdọ̀ ṣe ọgbà àjàrà rẹ, ati ọgbà olifi rẹ pẹlu. “Ọjọ́ mẹfa ni kí o fi ṣe iṣẹ́, ṣugbọn ní ọjọ́ keje, kí o sinmi; àtìwọ ati akọ mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ; kí ara lè tu ọmọ iranṣẹbinrin rẹ ati àlejò rẹ. “Máa ṣe akiyesi gbogbo ohun tí mo ti sọ fún ọ, má sì ṣe bọ oriṣa kankan, má tilẹ̀ jẹ́ kí n gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu rẹ. “Ìgbà mẹta ni o níláti máa ṣe àjọ̀dún fún mi ní ọdọọdún. O níláti máa ṣe àjọ̀dún àìwúkàrà; gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni o gbọdọ̀ fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ ninu oṣù Abibu, nítorí pé ninu oṣù náà ni o jáde ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo. “O gbọdọ̀ ṣe àjọ̀dún ìkórè nígbà tí o bá kórè àkọ́so àwọn ohun tí o gbìn sinu oko rẹ. “Ní òpin ọdún, nígbà tí o bá parí ìkórè gbogbo èso oko rẹ, o gbọdọ̀ ṣe àjọ̀dún ìkórè. Ẹẹmẹta ní ọdọọdún ni gbogbo ọkunrin yín níláti wá siwaju èmi OLUWA Ọlọrun yín. “Nígbà tí o bá fi ohun ẹlẹ́mìí rúbọ sí mi, burẹdi tí o bá fi rúbọ pẹlu rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí kò ní ìwúkàrà ninu, ọ̀rá ẹran tí o bá fi rúbọ sí mi kò sì gbọdọ̀ kù di ọjọ́ keji. “Ohunkohun tí o bá kọ́ kórè ninu oko rẹ, ilé OLUWA Ọlọrun rẹ ni o gbọdọ̀ mú un wá. “O kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi wàrà ìyá rẹ̀.