ẸSITA 5:1-3

ẸSITA 5:1-3 YCE

Ní ọjọ́ kẹta, Ẹsita wọ aṣọ oyè rẹ̀, ó dúró ní àgbàlá ààfin ọba, ó kọjú sí gbọ̀ngàn ọba. Ọba jókòó lórí ìtẹ́ ninu gbọ̀ngàn rẹ̀, ó kọjú sí ẹnu ọ̀nà. Nígbà tí ó rí Ẹsita tí ó dúró ní ìta, inú rẹ̀ dùn sí i, ọba na ọ̀pá oyè tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ sí i, Ẹsita sì na ọwọ́, ó fi kan ṣóńṣó ọ̀pá náà. Ọba bi ayaba Ẹsita pé, “Ẹsita, kí ló dé? Kí ni ẹ̀dùn ọkàn rẹ? A óo fún ọ, títí dé ìdajì ìjọba mi.”