EFESU 3:12-21

EFESU 3:12-21 YCE

Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìgboyà láti dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun. A sì ní ìdánilójú pé a ti rí ààyè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nípa igbagbọ. Nítorí èyí, mò ń gbadura pé kí ọkàn yín má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìpọ́njú tí mò ń rí nítorí yín. Ohun ìṣògo ni èyí jẹ́ fun yín. Nítorí èyí ni mo ṣe ń fi ìkúnlẹ̀ gbadura sí Baba, tí à ń fi orúkọ rẹ̀ pe gbogbo ìdílé lọ́run ati láyé. Mò ń gbadura pé, gẹ́gẹ́ bíi títóbi ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní agbára Ẹ̀mí rẹ̀ tí yóo fún ọkàn yín ní okun; kí Kristi fi ọkàn yín ṣe ilé nípa igbagbọ kí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu ìfẹ́, kí ìpìlẹ̀ ìgbé-ayé yín jẹ́ ti ìfẹ́, kí ẹ lè ní agbára, pẹlu gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun, láti mọ bí ìfẹ́ Kristi ti gbòòrò tó, bí ó ti gùn tó, bí ó ti ga tó, ati bí ó ti jìn tó; kí ẹ lè mọ bí ìfẹ́ Kristi ti tayọ ìmọ̀ ẹ̀dá tó, kí ẹ sì lè kún fún gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọrun. Ògo ni fún ẹni tí ó lè ṣe ju gbogbo nǹkan tí à ń bèèrè, ati ohun gbogbo tí a ní lọ́kàn lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ ninu wa. Kí ògo yìí wà fún un ninu ìjọ ati ninu Kristi Jesu láti ìrandíran títí laelae. Amin.