EFESU 2:11-12

EFESU 2:11-12 YCE

Nítorí náà, ẹ ranti pé nígbà kan rí, ẹ jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí ipò tí a bi yín sí. Àwọn tí wọ́n kọlà ti ara, tí wọ́n fi ọwọ́ kọ sì ń pè yín ní aláìkọlà. Nígbà náà ẹ wà ní ipò ẹni tí kò mọ Kristi. Ẹ jẹ́ àjèjì sí àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ Israẹli. Àwọn majẹmu tí ó ní ìlérí Ọlọrun ninu sì tún ṣe àjèjì si yín. Ẹ wà ninu ayé láìní ìrètí ati láìní Ọlọrun.