Ẹ̀yin tí ẹ ti di òkú nípa ẹ̀ṣẹ̀ yín, tí ẹ jẹ́ aláìkọlà nípa ti ara, ni Ọlọrun ti sọ di alààyè pẹlu Kristi. Ọlọrun ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Ó ti pa àkọsílẹ̀ tí ó lòdì sí wa rẹ́, ó mú un kúrò, ó kàn án mọ́ agbelebu. Ó gba agbára lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí ojú ọ̀run: ati ìjọba ni, ati àwọn alágbára wọ̀n-ọn-nì; ó bọ́ wọn síhòòhò, ó fi wọ́n ṣẹ̀sín ní gbangba, nígbà tí ó ti ṣẹgun wọn lórí agbelebu. Nítorí náà ẹ má gbà fún ẹnikẹ́ni kí ó máa darí yín nípa nǹkan jíjẹ tabi nǹkan mímu, tabi nípa ọ̀rọ̀ àjọ̀dún tabi ti oṣù titun tabi ti Ọjọ́ Ìsinmi. Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àwòjíìjí ohun tí ó ń bọ̀, ṣugbọn nǹkan ti Kristi ni ó ṣe pataki. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni da yín lẹ́bi, kí ó sọ fun yín pé kí ẹ máa fi ìyà jẹ ara yín, kí ẹ máa sin àwọn angẹli. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń ṣe ìgbéraga nípa ìran tí ó ti rí, ó ń gbéraga lásán nípa nǹkan ti ara rẹ̀; kò dì mọ́ ẹni tíí ṣe orí, tí ó mú kí gbogbo ara, ati iṣan, ati ẹran-ara wà pọ̀, tí ó ń mú un dàgbà bí Ọlọrun ti fẹ́. Bí ẹ bá ti kú pẹlu Kristi sí àwọn ìlànà ti ẹ̀mí tí a kò rí, kí ló dé tí ẹ fi tún ń pa oríṣìíríṣìí èèwọ̀ mọ́? “Má fọwọ́ kan èyí,” “Má jẹ tọ̀hún,” “Má ṣegbá, má ṣàwo?” Gbogbo àwọn nǹkan wọnyi yóo ṣègbé bí ẹ bá ti lò wọ́n tán. Ìlànà ati ẹ̀kọ́ eniyan ni wọ́n. Ó lè dàbí ẹni pé ọgbọ́n wà ninu àwọn nǹkan wọnyi fún ìsìn ti òde ara ati fún ìjẹra-ẹni-níyà ati fún ìkóra-ẹni-níjàánu. Ṣugbọn wọn kò ṣe anfaani rárá láti jẹ́ kí eniyan borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara.
Kà KOLOSE 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: KOLOSE 2:13-23
4 Ọjọ
Awọn Ere Awọn Nkan Nla Meji ti soju iṣẹlẹ ti ọkanlẹlo diẹ ninu Bibeli, ti o soju awọn ohun orisun ara Jesu ti a gbọdọ ni a gbẹ nipa lati wa ni Kristiani ti o le ṣe iṣẹlẹ ti o dara. Nitorina pe a le soju iṣẹlẹ ọlọgbo lati mọ bii o le kede awọn iṣeduro ti o yẹ lati gba lati gba iṣẹlẹ ni ẹjẹ rere rẹ."
4 Awọn ọjọ
Ètò ìwé-kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yànnàná ìwé tí Paulu kọ sí àwọn ará Kólósè, níbi tí ó ti tako ẹ̀kọ́ òdì tó fi ń rán wa létí pé Jésù - ẹni gíga jùlọ àti alóhun-gbogbo lódùlódù - ṣẹ̀dá àgbáyé, ó sì gba aráyé là. Paulu tún ṣètò ọgbọ́n ìṣàmúlò lórí ìbáṣepọ̀ láàárín ẹbí, àdúrà, ìgbé-ayé ìwà mímọ́, àti ohun tó túmọ̀ sí láti wà ní ìṣọ̀kan nínú ìfẹ́.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò