ÌṢE ÀWỌN APOSTELI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Àfikún ati ìgbésẹ̀ siwaju àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sinu Ìyìn Rere Luku ni Ìṣe Àwọn Aposteli jẹ́. Kókó ète ìwé náà ni láti sọ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe darí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu láti tan Ìròyìn Ayọ̀ náà káàkiri ní Jerusalẹmu ati ní Judia, títí dé òpin ayé (1:8). Ìtàn ìdìde ati ìdàgbàsókè igbagbọ ni, bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn Juu títí ó fi di igbagbọ gbogbo àgbáyé. Ọ̀kan ninu àwọn ohun tí ó jẹ ẹni tí ó kọ ìwé yìí lógún ni láti mú kí ó dá àwọn òǹkàwé rẹ̀ lójú pé àwọn onigbagbọ kì í ṣe òṣèlú onírúkèrúdò tí yóo dojú ìjọba Romu délẹ̀, àtipé igbagbọ ni ìmúṣẹ ìsìn àwọn Juu.
A lè pín ìwé Ìṣe Àwọn Aposteli sí ọ̀nà mẹta tí ó ń fi hàn bí àwọn ibi tí a ti ń waasu Ìròyìn Ayọ̀ nípa Jesu ti ń gbòòrò sí i, ati bí a ti ṣe fi ìdí ìjọ Ọlọrun múlẹ̀: (1) Ìbẹ̀rẹ̀ ìdàgbàsókè ati ìtànkálẹ̀ igbagbọ ní Jerusalẹmu lẹ́yìn ìgòkè-re-ọ̀run Jesu; (2) bí igbagbọ ṣe tàn káàkiri àwọn agbègbè mìíràn ní Palẹstini (3) ati bí ó ṣe tún tàn káàkiri àwọn agbègbè tí ó yí òkun Mẹditarenia ká, títí ó fi dé Romu.
Nǹkankan pataki tíí máa ń jẹ jáde lemọ́lemọ́ ninu Ìṣe Àwọn Aposteli ni iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó fi tagbára-tagbára sọ̀kalẹ̀, tí ó sì bà lé àwọn onigbagbọ lórí ní Jerusalẹmu ní ọjọ́ Pẹntikọsti. Ẹ̀mí Mímọ́ yìí ní ń darí ìjọ ati àwọn adarí ìjọ, tí ó sì ń fún wọn ní agbára ninu gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a sọ nípa rẹ̀ ninu ìwé yìí. A ṣe àkójọ iṣẹ́ tí àwọn onigbagbọ àkọ́kọ́ níláti jẹ́ ní ṣókí ninu àwọn iwaasu bíi mélòó kan. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sinu ìwé Ìṣe Àwọn Aposteli fi agbára iṣẹ́ tí wọn ń jẹ́ yìí hàn ninu ìgbé-ayé àwọn onigbagbọ ati ìrẹ́pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ìpalẹ̀mọ́ fún ìjẹ́rìí 1:1-26
a. Àṣẹ ìkẹyìn tí Jesu pa ati ìlérí tí ó ṣe 1:1-14
b. Ẹni tí ó gba ipò Judasi 1:15-26
Ìjẹ́rìí ní Jerusalẹmu 2:1–8:3
Ìjẹ́rìí ní Judia ati ní Samaria 8:4–12:25
Iṣẹ́ Paulu 13:1–28:31
a. Ìrìn àjò ìjíyìn rere kinni 13:1–14:28
b. Àjọ tí wọ́n ṣe ní Jerusalẹmu 15:1-35
d. Ìrìn àjò ìjíyìn rere keji 15:36–18:22
e. Ìrìn àjò ìjíyìn rere kẹta 18:23–21:16
ẹ. Paulu ṣe ẹ̀wọ̀n ní Jerusalẹmu, Kesaria ati Romu 21:17–28:31

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa