ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 14:8-10

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 14:8-10 YCE

Ọkunrin kan wà ní ìjókòó ní Listira tí ó yarọ. Láti ìgbà tí wọ́n ti bí i ni ó ti yarọ, kò fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn rí. Ọkunrin yìí fetí sílẹ̀ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀. Paulu wá tẹjú mọ́ ọn lára, ó rí i pé ó ní igbagbọ pé wọ́n lè mú òun lára dá. Ó bá kígbe sókè, ó ní, “Dìde, kí o dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ bí eniyan.” Ni ọkunrin arọ náà bá fò sókè, ó bá ń rìn.