Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ lọ́nàkọnà nípa ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí kí ọjọ́ Oluwa tó dé, ọ̀tẹ̀ nípa ti ẹ̀sìn níláti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, kí Ẹni Ibi nnì, ẹni ègbé nnì sì farahàn. Yóo lòdì sí ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti Ọlọrun tabi tí ó jẹ mọ́ ti ẹ̀sìn. Yóo gbé ara rẹ̀ ga ju èyíkéyìí ninu àwọn oriṣa lọ; yóo tilẹ̀ lọ jókòó ninu Tẹmpili Ọlọrun, yóo sì fi ara hàn pé òun ni Ọlọrun. Ẹ ranti pé a ti sọ gbogbo èyí fun yín nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín. Ǹjẹ́ nisinsinyii, ẹ mọ ohun tí ó ń ká a lọ́wọ́ kò, tí kò jẹ́ kí ó farahàn títí àkókò rẹ̀ yóo fi tó. Nítorí nǹkan àṣírí kan tíí máa fa rúkèrúdò ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́, ṣugbọn ẹni tí ó ń ká a lọ́wọ́ kò wà, kò ì kúrò lọ́nà.
Kà TẸSALONIKA KEJI 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: TẸSALONIKA KEJI 2:3-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò