TẸSALONIKA KINNI 4:14-16

TẸSALONIKA KINNI 4:14-16 YCE

Nítorí bí a bá gbàgbọ́ pé Jesu kú, ó sì jinde, bẹ́ẹ̀ gan-an ni Ọlọrun yóo mú àwọn tí wọ́n ti kú ninu Jesu wà pẹlu rẹ̀. Nítorí à ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fun yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Oluwa, pé àwa tí a bá wà láàyè, tí a bá kù lẹ́yìn nígbà tí Oluwa bá farahàn, kò ní ṣiwaju àwọn tí wọ́n ti kú. Nítorí nígbà tí ohùn àṣẹ bá dún, Olórí àwọn angẹli yóo fọhùn, fèrè Ọlọrun yóo dún, Oluwa fúnrarẹ̀ yóo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Àwọn òkú ninu Jesu ni yóo kọ́kọ́ jinde.