À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí gbogbo yín, a sì ń ranti yín ninu adura wa nígbà gbogbo. Ninu adura wa sí Ọlọrun Baba wa, à ń ranti bí igbagbọ yín ti ń mú kí ẹ ṣiṣẹ́, tí ìfẹ́ yín ń jẹ́ kí ẹ ṣe akitiyan, tí ìrètí tí ẹ ní ninu Oluwa wa Jesu Kristi sì ń mú kí ẹ ní ìfaradà. Ẹ̀yin ará, àyànfẹ́ Ọlọrun, a mọ̀ pé Ọlọrun ni ó yàn yín. Nígbà tí a mú ìyìn rere wá sí ọ̀dọ̀ yín, a kò mú un wá pẹlu ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan; ṣugbọn pẹlu agbára ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni, ati pẹlu ọpọlọpọ ẹ̀rí tí ó dáni lójú. Ẹ̀yin náà kúkú ti mọ irú ẹni tí a jẹ́ nítorí tiyín nígbà tí a wà láàrin yín. Ẹ̀yin náà wá ń fara wé wa, ẹ sì ń fara wé Oluwa. Láàrin ọpọlọpọ inúnibíni ẹ gba ọ̀rọ̀ ìyìn rere tayọ̀tayọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.
Kà TẸSALONIKA KINNI 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: TẸSALONIKA KINNI 1:2-6
5 Days
Hosanna Wong knows firsthand what feeling unseen, unworthy, and unloved is like. In this 5-day plan, she unpacks nine names God calls you and offers practical, down-to-earth encouragement to help you expose lies, see yourself through God’s lens, and live with a newfound posture and purpose.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò