Filistini náà sì ń rìn bọ̀ wá pàdé Dafidi; ẹni tí ń ru asà rẹ̀ sì wà níwájú rẹ̀. Nígbà tí ó rí Dafidi dáradára, ó wò ó pé ọmọ kékeré kan lásán, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́wà ni, nítorí náà, ó fojú tẹmbẹlu rẹ̀. Ó bi Dafidi pé, “Ṣé ajá ni mí ni, tí o fi ń mú ọ̀pá tọ̀ mí bọ̀?” Ó fi Dafidi bú ní orúkọ oriṣa rẹ̀, ó sì wí pé, “Sún mọ́ mi níhìn-ín, n óo sì fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ati ẹranko jẹ.” Dafidi dáhùn pé, “Ìwọ ń bọ̀ wá bá mi jà pẹlu idà ati ọ̀kọ̀, ṣugbọn èmi ń bọ̀ wá pàdé rẹ ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun Israẹli, tí ò ń pẹ̀gàn.
Kà SAMUẸLI KINNI 17
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: SAMUẸLI KINNI 17:41-45
5 Days
King David is described in the New Testament as a man after God’s own heart, meaning that he aligned his own heart with that of God’s. As we study David’s life, our goal for this series is to analyze the things David did in 1 & 2 Samuel in order to mold our hearts after God’s and resemble the same intensity of focus and spirit that David showcased throughout his life.
6 Awọn ọjọ
Ṣe àwárí nínú ìgbésíayé Jeremiah àti Dafidi, pé o kò kéré jù láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésí-ayé èrèdí rẹ, sísin Ọlọ́run pẹ̀lú ohun tí o ní, níbi tí o wà. Kọ́ nipa ohun ìmúrasílẹ̀ fún èrèdí rẹ túmọ̀ sí, bí o ti ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn tí yóò bà á jẹ́, kí o sì múra sílẹ̀ láti gbé ìgbésí-ayé onítumọ̀, afògo-fún-Ọlọ́run tí yóò bùkún ayé.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò