PETERU KINNI 3:8-16

PETERU KINNI 3:8-16 YCE

Ní gbolohun kan, ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ ni ojú àánú. Ẹ ní ìfẹ́ sí ara yín. Ẹ máa ṣoore. Ẹ ní ọkàn ìrẹ̀lẹ̀. Ẹ má fi burúkú gbẹ̀san burúkú, tabi kí ẹ fi àbùkù kan ẹni tí ó bá fi àbùkù kàn yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ wọn ní rere ni. Irú ìwà tí a ní kí ẹ máa hù nìyí, kí ẹ lè jogún ibukun tí Ọlọrun ṣèlérí fun yín. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹni tí ó bá fẹ́ ìgbé-ayé tí ó wù ú, tí ó fẹ́ rí ọjọ́ tí ó dára, ó níláti kó ara rẹ̀ ni ìjánu pẹlu ọ̀rọ̀ burúkú sísọ, kí ó má fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Ó níláti yipada kúrò ninu ìwà burúkú, kí ó máa hu ìwà rere. Ó níláti máa wá alaafia, kí ó sì máa lépa rẹ̀. Nítorí Oluwa ń ṣọ́ àwọn olódodo, ó sì dẹ etí sí ẹ̀bẹ̀ wọn. Ṣugbọn ojú Oluwa kan sí àwọn tí ó ń ṣe burúkú.” Ta ni lè ṣe yín ní ibi tí ẹ bá ní ìtara fún ohun tíí ṣe rere? Ṣugbọn bí ẹ bá tilẹ̀ jìyà nítorí òdodo, ẹ ṣe oríire. Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọn ń jẹ yín níyà, kí ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú. Ṣugbọn ẹ fi ààyè fún Kristi ninu ọkàn yín bí Oluwa. Ẹ múra nígbà gbogbo láti dáhùn bí ẹnikẹ́ni bá bi yín ní ìbéèrè nípa ìrètí tí ẹ ní. Ṣugbọn kí ẹ dáhùn pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní àìdára, ojú yóo ti àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa yín, nígbà tí wọn bá rí ìgbé-ayé yín gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ.