PETERU KINNI 1:18-25

PETERU KINNI 1:18-25 YCE

Nítorí ẹ mọ̀ pé kì í ṣe ohun tí ó lè bàjẹ́, bíi fadaka ati wúrà, ni a fi rà yín pada kúrò ninu ìgbé-ayé asán tí ẹ jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín. Ohun tí a fi rà yín ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹ̀jẹ̀ iyebíye bíi ti ọ̀dọ́-aguntan tí kò ní àléébù, tí kò sì ní àbààwọ́n. Kí á tó dá ayé ni a ti yan Kristi fún iṣẹ́ yìí. Ṣugbọn ní àkókò ìkẹyìn yìí ni ó tó fi ara hàn nítorí tiyín. Ẹ̀yin tí ẹ ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọrun tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú gbọ́, tí ó ṣe é lógo, kí igbagbọ ati ìrètí yín lè wà ninu Ọlọrun. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ nípa ìgbọràn sí òtítọ́, tí ẹ sì ní ìfẹ́ àìlẹ́tàn sí àwọn onigbagbọ ara yín, ẹ fi tinútinú fẹ́ràn ọmọnikeji yín. A ti tún yín bí! Kì í ṣe èso tí ó lè bàjẹ́ ni a fi tún yín bí bíkòṣe èso tí kò lè bàjẹ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó wà láàyè, tí ó sì wà títí. Nítorí, “Gbogbo ẹlẹ́ran-ara dàbí Koríko, gbogbo ògo rẹ̀ dàbí òdòdó. Koríko a máa gbẹ, òdòdó a máa rẹ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ Oluwa yóo wà títí lae.” Òun ni ọ̀rọ̀ tí à ń waasu rẹ̀ fun yín.