Ǹ báà ní ẹ̀bùn wolii, kí n ní gbogbo ìmọ̀, kí n mọ gbogbo àṣírí ayé, kí n ní igbagbọ tí ó gbóná tóbẹ́ẹ̀ tí ó lè ṣí òkè ní ìdí, tí n kò bá ní ìfẹ́, n kò já mọ́ nǹkankan. Ǹ báà kò gbogbo ohun tí mo ní, kí n fi tọrẹ, kódà kí n fi ara mi rú ẹbọ sísun, bí n kò bá ní ìfẹ́, kò ṣe anfaani kankan fún mi. Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, a máa ṣe oore. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í ṣe ìgbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kì í fọ́nnu. Ìfẹ́ kì í ṣe ohun tí kò tọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í hùwà ìmọ-tara-ẹni-nìkan. Kì í tètè bínú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí eniyan lọ́rùn. Ìfẹ́ kì í fi nǹkan burúkú ṣe ayọ̀, ṣugbọn a máa yọ̀ ninu òtítọ́. Ìfẹ́ a máa fara da ohun gbogbo, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa ní ìrètí ninu ohun gbogbo, a sì máa foríti ohun gbogbo.
Kà KỌRINTI KINNI 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: KỌRINTI KINNI 13:2-7
3 Days
Celebrating love goes beyond a particular date; it is a life that constantly reminds others that God's love came to heal, restore, and give us a life that proclaims his goodness. I invite you to navigate a three-day study of what love represents and what it looks like to love others as God intends us to.
7 Awọn ọjọ
Ọkàn nínú awọn ọrọ ti an ṣilo julọ ni "Ìfẹ". An tọka sí ní tó fí aimọkan wa hàn. A un fi ìwà inú, ìbálòpọ̀ ati ṣiṣe ifihan ìfẹ dipo rẹ; eleyii tí àwon Olorin, Eléré ati akowe ìfẹ fín ta ọjà wọn. Sugbọn, Ọlọrun (nínú ìṣẹ̀dá ati ìwà) ni ife, àyàfi tia ba ri ifẹ gẹgẹbi Irisi Bibeli a' ṣi jina sí ririn nínú ìfẹ.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò