ṣugbọn ní tiwa, àwa ń waasu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu. Ohun ìkọsẹ̀ ni iwaasu wa yìí jẹ́ lójú àwọn Juu, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ sì ni lójú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù; ṣugbọn lójú àwọn tí Ọlọrun pè, ìbáà ṣe Juu tabi Giriki, Kristi yìí ni agbára Ọlọrun, òun ni ọgbọ́n Ọlọrun. Nítorí agọ̀ Ọlọrun gbọ́n ju eniyan lọ, àìlágbára Ọlọrun sì lágbára ju eniyan lọ! Ẹ̀yin ará, ẹ wo ọ̀nà tí Ọlọrun gbà pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ ninu yín ni ọlọ́gbọ́n gẹ́gẹ́ bí èrò ẹ̀dá, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe alágbára, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe ọlọ́lá. Ṣugbọn Ọlọrun ti yan àwọn nǹkan tí ayé kà sí agọ̀ láti fi dójú ti àwọn ọlọ́gbọ́n, ó yan àwọn nǹkan tí kò lágbára ti ayé, láti fi dójú ti àwọn alágbára; bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun yan àwọn ẹni tí kò níláárí ati àwọn ẹni tí kò já mọ́ nǹkankan rárá, àwọn tí ẹnikẹ́ni kò kà sí, láti rẹ àwọn tí ayé ń gbé gẹ̀gẹ̀ sílẹ̀. Ìdí tí Ọlọrun fi ṣe báyìí ni pé kí ẹnikẹ́ni má baà lè gbéraga níwájú òun. Nípa iṣẹ́ Ọlọrun, ẹ̀yin wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Òun ni Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n wa ati òdodo wa. Òun ni ó sọ wá di mímọ́, tí ó dá wa nídè. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pe: “Ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe ìgbéraga, kí ó ṣe ìgbéraga nípa ohun tí Oluwa ṣe.”
Kà KỌRINTI KINNI 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: KỌRINTI KINNI 1:23-31
5 Days
Seeking Daily the Heart of God is a 5 day reading plan intended to encourage, challenge, and help us along the path of daily living. As Boyd Bailey has said, "Seek Him even when you don't feel like it, or when you are too busy and He will reward your faithfulness." The Bible says, "Blessed are they who keep his statutes and seek him with all their heart." Psalm 119:2
7 Days
Nearly everyone agrees that this world is broken. But what if there’s a solution? This seven-day Easter plan begins with the unique experience of the thief on the cross and considers why the only real answer to brokenness is found in the execution of an innocent man: Jesus, the Son of God.
7 Awọn ọjọ
Ìgbé ayé ninú Kristi láìsí iyemeji tayọ ìgbé ayé ẹlẹran àrà, ẹsìn tabi aṣa bi ìwà mimọ ati titẹle òfin. Ṣugbọn o jẹ ìgbé ayé àgbàrá ati Ọgbọn, ìgbé ayé tí a ni lati inú iyé ainipẹkun Ọlọrun. Kristi wà sáyé láti gbé 'nú rẹ àti lati fi ìyè hàn onigbagbọ nínú rẹ, onigbagbọ nínú Kristi jẹ alabapin àyè yìí nipasẹ dídì Atunbi ati Ẹmí Mímọ t'in gbé inú wọn.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò