Àwọn ohun mẹ́fà wà tí OLúWA kórìíra,
ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i,
Ojú ìgbéraga,
ahọ́n tó ń parọ́
ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,
ọkàn tí ń pète ohun búburú,
ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,
ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu
àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan.