1
Òwe 12:25
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
BMYO
Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Òwe 12:25
2
Òwe 12:1
Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.
Ṣàwárí Òwe 12:1
3
Òwe 12:18
Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá.
Ṣàwárí Òwe 12:18
4
Òwe 12:15
Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.
Ṣàwárí Òwe 12:15
5
Òwe 12:16
Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.
Ṣàwárí Òwe 12:16
6
Òwe 12:4
Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà.
Ṣàwárí Òwe 12:4
7
Òwe 12:22
OLúWA kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́.
Ṣàwárí Òwe 12:22
8
Òwe 12:26
Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.
Ṣàwárí Òwe 12:26
9
Òwe 12:19
Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.
Ṣàwárí Òwe 12:19
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò