“Ọjọ́ náà ń bọ,” ni OLúWA wí,
“tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá.
Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá.
Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀,
tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèké.
Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Israẹli ènìyàn mi padà bọ̀.