Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Rom 8:3

Níní Ìrírí Ìbádọ́ọ̀rẹ́ Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ọjọ́ Márùn-ún
Sé ò n la àkókò aginjù kọjá, láì rí omi tàbí sẹ́lẹ̀rú fún ọkàn rẹ? Báwo ni ìbá ṣe rí tí àsìkò yìí bá ní ìrètí tí ó ga jù lọ: nípasẹ mímọ Ọlọ́run jinlẹ̀, ni ògidì ati tọkàntọkàn? Ètò yìí ń gba'ni ní ìyànjú pé àkọ́kọ̀ yìí kìí ṣe lásán bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ rò pé o kò tẹ̀ sí iwájú. Nítorí pé kò sí ọ̀nà tí ò kò báa rìn, Ọlọ́run n rìn pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bíi Olùtùnú, Afúniníyè & Ọ̀rẹ́.

Já Ara Rẹ Gbà Kúrò Lọ́wọ́ Owú Ètò Kíkà Ọlọ́jọ́-Mẹ́fà Látọwọ́ Anna Light
Ọjọ́ mẹ́fà
Ní àkókò yí, ǹkan tó dára nípa ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ní wọ́n fihàn fún wa láti rí, àti wípé àfiwé tí a bá ṣe pẹ̀lú ayé tiwa a máa mú owú jẹyọ. O kò fẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí máa jọba nínú ayé rẹ, àmọ́ kí ló máa ṣe sí àwọn ìjàmbá tó lè wá nípasẹ̀ owú látọ̀dọ̀ ẹlòmíràn sí ọ? Nínú ètò kíkà yí, o máa rí àwọn ọ̀nà tí o lè gbà borí owú, pa ọkàn rẹ mọ́, pẹ̀lú òmìnira.

Ìṣẹ́gun l'órí Ikú
Ọjọ́ Méje
Wọ́n ti máa ń sọ fún wa pé, "Bẹ́ẹ́ ní ayé rí," àmọ́ àwọn àṣamọ̀ báyìí kìí dín ìrora tó wà nínú pípa àdánù ẹni tí a fẹ́ràn kù. Kọ́ láti sá tọ Ọlọ́run lọ nígbàtí o bá ń d'ojúkọ àwọn ìpèníjà ayé tó le jù.

Rin Ìrìn-Àjò Rẹ Láì Sí Ẹrú Wúwo
Ọjọ́ Méje
Ní àkókò pọ̀pọ̀sìnsìn ọ́dún Kérésì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló máa ń fajúro nítorí wàhálà àti àníyàn tó jẹmọ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹbí, làálàá ìṣúná, ìpinnu ìdágìrì àti ìjákulẹ̀ nípa àwọn ìrètí wa. Wàyì o, gbé ìgbésẹ. Mí kanlẹ̀. Bẹ̀rẹ̀ ètò Bíbélì Life.Church yí láti ní òye wípé ẹrù náà tó ń rìn wá mọ́lẹ̀ lè jẹ́ èyí tí Ọlọ́run kò rán wa láti gbé rárá. A ò bá jọ̀wọ́ ẹrù wúwo yìí. Jẹ́ kí a rin ìrìn àjò tó fúyẹ́.

Ìgbésẹ̀ Mẹ́fà Lọsí Ìdarí Tó Dára jù
Ọjọ́ méje
Ǹjẹ́ o ṣe tán láti dàgbà si gẹ́gẹ́bí olùdarí? Craig Groeschel ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́fà tí a fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nínú Bíbélì èyí tí ẹnikẹ́ni le tẹ̀lé láti di olùdarí tó dára. Ṣàwárí ìséra-ẹni láti bẹ̀rẹ̀, ìgboyà láti dúró, ẹnìkan tí o lè fún ní ipá, ètò kan tí o lè dá sílẹ̀, ìbárẹ́ titun tí o lè bẹ̀rẹ̀, àti àwọn ewu tí o nílò láti kojú.