Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mat 25:35

Rúùtù: Ìtàn Ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run
Ọjọ́ 7
Bóyá ọ̀kan l'ára àwọn ìtàn kúkúrú tí ó wunilori jù lọ, ní ìwé Rúùtù tí ó jẹ́ àkọsílẹ̀ ti ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run. Iwe Rúùtù jẹ́ ìtàn tí ó yanilẹ́nu bí Ọlọ́run ṣe nlo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn lásán láti ṣe iṣẹ́ ìfẹ́ Òun ti o jé Ọba Aláṣẹ. Pẹ̀lú àwọn àkàwé tí ó rẹwà ti ìfẹ́ àti ìrúbọ Krístì fún àwọn ènìyàn Rẹ, a fi hàn wá ipele tí Ọlọ́run lọ láti ra àwọn ọmọ Rẹ̀ padà.

Kí Ni Ète Mi? Kíkọ́ Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Àwọn Ẹlòmíràn
Ọjọ́ Méje
Ye ète rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jésù: láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn. Lórí awọn ọjọ méje, a yoo tu awọn àkórí ti ìjọsìn ti ara ẹni, ìyípadà, aanu, iṣẹ, ati ìdájọ. Ìpàdé kọ̀ọ̀kan máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà kan láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ni ìfòjúsùn sórí ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ náà, àyọkà kan tàbí méjì láti inú ìwé mímọ́, èrò kan láti inú ojú ìwòye ẹ̀kọ́ ìsìn, àti àwọn ọ̀nà láti fi sílò kí o sì dáhùn padà sí kíkà náà.