Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Jak 1:7

ÌGBÀGBỌ́; Ọ̀nà láti WU ỌLỌ́RUN
3 Awọn ọjọ
Ìrìn-àjò Kristẹni jẹ́ èyí tí a kò ti rí Ọlọ́run lójú-kojú, a máa ń bá A ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Ọ̀nà kan ṣoṣo láti wu Ọlọ́run nínú ìrìn wa pẹ̀lú Rẹ̀ ni ìgbàgbọ́, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé a kò lè rí I pẹ̀lú ojú wa nípa tara. À ń gbọ́ Ọ nípa ìgbàgbọ́, à ń bá A sọ̀rọ̀ nípa Ìgbàgbọ́, a sì ń tọ̀ Ọ́ lọ nínú àdúrà nípa ìgbàgbọ́.

Ọlọrun, Èmi Ńkọ́?
Ọjọ marun
Nígbà tá a bá rò pé a ti jìnnà síbi tá a yẹ ká máa gbé, tí ohùn ìfiwéra sì túbọ̀ ń dún bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, a kì í sábà rí i pé Ọlọ́run wà láàárín wa. Àwọn àkókò yìí gan-an ni ìgbàgbọ́ wa máa ń lágbára jù lọ. Ka àdúrà yìí kó o sì rí ìṣírí gbà bó o ṣe ń dúró de Ọlọ́run.

Ayọ̀ fún Ìrìnàjò náà: Wíwá Ìrètí ní Àárín Ìdánwò
Ọjọ́ Méje
A lè má rí i tàbí ní í l'érò ní ìgbà gbogbo, ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa ní ìgbà gbogbo... kódà ní ìgbà tí a bá ń la àwọn ìṣòro kọjá. Nínú ètò yìí, Amy LaRue Olùdarí Finding Hope ṣe àkọsílẹ̀ àtọkànwá nípa ìjàkadì ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú ìwà bárakú àti bí ayọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹyọ ní àwọn àkókò tí ó nira jùlọ.

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ojo Méjìlá
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ ìfarajìn onínú dídùn sí ìgbésí-ayé àdúrà tó jinlẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbọ́ ohùn Ọlọ́run. Ọlọ́run fẹ́ kí a ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí kò ní ìdíwọ́ jálẹ̀ ayée wa—ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò mú ìyàtọ̀ wá nínú ìṣísẹ̀, ìbáṣepọ̀, àti ìgbésí-ayé tó ní ìtumọ̀. Ètò yí kún fún àwọn ìtàn nípa bí a ti dé oókan àyà Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa!